Jóṣúà 23:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń se tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.

9. “Olúwa ti lé àwọn orílẹ̀ èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojú kọ yín.

10. Ọ̀kan nínú yín lé ẹgbẹ̀rún ọ̀ta, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín jà fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí.

11. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ sọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín.

Jóṣúà 23