9. Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè fi àwọn ará Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní Sílò ní Kénánì láti padà sí Gílíádì, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè wá.
10. Nígbà tí wọ́n wá dé Gélílótì ní ẹ̀bá Jọ́dánì ní ilẹ̀ Kénánì, àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jọ́dánì.
11. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti mọ pẹpẹ ní orí ààlà Kénánì ní Gélíótì ní ẹ̀bá Jọ́dánì ní ìhà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,
12. gbogbo àjọ Ísírẹ́lì péjọ ní Ṣílò láti lọ bá wọn jagun.
13. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rán Fínéhásì ọmọ Élíásárì àlùfáà, sí ilẹ̀ Gílíádì, sí Rúbẹ́nì, sí Gádì àti sí ìdajì ẹ̀yà Mánásè.
14. Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ti wọn jẹ́ olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
15. Nígbà tí wọ́n lọ sí Gílíádì-sí Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè wọ́n sì sọ fún wọn pé,
16. “Gbogbo àjọ ènìyàn Olúwa wí pe: ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì nípa yíyí padà kúró lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìsọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Olúwa.?
17. Ẹ̀sẹ̀ Péórì kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tíì wẹ ara wa mọ́ kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-àrùn ti jà láàárin ènìyàn Olúwa.!