30. Láti ara ẹ̀yà Ásíérì ni wọ́n ti fún wọn níMísálì, àti Ábídónì,
31. Hélíkátì àti Réhóbì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ mẹ́rin;
32. Láti ara ẹ̀yà Náfítanì ni a ti fún wọn níKedeṣì ní Gálílì (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Hámótì Dórì àti Kárítanì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́ta.”
33. Gbogbo ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Gáṣónì jẹ́ mẹ́talá, pẹ̀lú ilẹ́ pápá oko wọn.
34. Láti ara ẹ̀yà Sébúlónì ni a ti fún ìdílé Mérárì (tí í ṣe ìyókù ọmọ Léfì) ní:“Jókíníámù, Kárítà,
35. Dímínà àti Náhálálì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.