Jóṣúà 21:20-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ìyòókù ìdílé Kóhátì tí ó jẹ́ ọmọ Léfì ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù.

21. “Ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù wọ́n fún wọn ní Ṣẹ́kẹ́mù (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn) ati Gésérì,

22. Kíbásáímù àti Bẹti-Hórónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.

23. Láti ara ẹ̀yà Dánì ní wọ́n ti fún wọn ní Élítékè Gíbátónì,

24. Áíjálónìd àti Gati-Rímónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ mẹ́rin.

25. Láti ara ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní wọ́n ti fún wọn ní Tánákì àti Gati-Rímónì pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú méjì.”

26. Gbogbo ìlú mẹ́wẹ̀wá yìí àti ilẹ̀ pápá wọn ni a fi fún ìyókù ìdílé Kóhátì.

27. Àwọn ọmọ Gáṣóní idile àwọn ọmọ Lefi ní wọ́n fún lára:“ìdajì ẹ̀yà Mánásè,Gólánì ní Básánì (ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Be Ésítarà pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn jẹ́ méjì;

28. Láti ara ẹ̀yà Ísákárì ni wọ́n ti fún wọn ní,Kísíónì Dábérátì,

29. Járímútì àti Ẹni Gánímù, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ mẹ́rin.

Jóṣúà 21