Jóṣúà 19:32-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Ìpín kẹfà jáde fún Náfítalì, agbo ilé ní agbo ilé:

33. Ààlà wọn lọ láti Hẹ́lẹ́fì àti igi ńlá ní Sááná nímù; kọjá lọ sí Ádámì Nékébù àti Jábínẹ́ẹ́lì dé Lákúmì, ó sì pín ní Jọ́dánì.

34. Ààlà náà gba ìhà ìwọ̀-oòrùn lọ sí Ásínótì, Tabori ó sì jáde ní Húkókì. Ó sì dé Sébúlúnìe ní ìhà gúsù, Ásíẹ́rì ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Jọ́dánì ní ìhà ìlà-oòrùn.

35. Àwọn ìlú olódi sì Sídímù, Sérì, Hámátì, Rákátì, Kínérétì,

36. Ádámà, Rámà Hásórì,

Jóṣúà 19