Jóṣúà 18:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ó tẹ̀ṣíwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Árábà, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù.

19. Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Bẹti-Hógíládì, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jọ́dánì ní gúsù. Èyí ni ààlà ti gúsù.

20. Odò Jọ́dánì sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn.Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó ṣàmì sí ìní àwọn ìdílé Bẹ́ńjámínì ní gbogbo àwọn àyíká wọn.

21. Ẹyà Bẹ́ńjámínì ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí:Jẹ́ríkò, Bẹti-Hógílà, Emeki-Késísì,

Jóṣúà 18