Jóṣúà 13:32-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Èyí ni ogún tí Mósè fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ní ìhà kéjì Jọ́dánì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò.

33. Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yà Léfì, Mósè kò fi ogún fún un; Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní ogún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

Jóṣúà 13