Jóṣúà 10:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣaájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí Olúwa gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú Olúwa jà fún Ísírẹ́lì!

15. Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì padà sí ibùdó ní Gílígálì.

16. Ní báyìí àwọn ọba Ámórì márùn-ún ti sá lọ, wọ́n sì fara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Mákédà,

17. Nígbà tí wọ́n sọ fún Jósúà pé, a ti rí àwọn ọba máràrùn, ti ó fara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Mákédà,

18. ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ.

Jóṣúà 10