Jóṣúà 1:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nígbà náà ni wọ́n dá Jósúà lóhùn pé, “Ohunkóhun tí ìwọ pa láṣẹ fún wa ni àwa yóò ṣe; ibikíbi tí ìwọ bá rán wa ni àwa yóò lọ.

17. Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ran sí Móṣè nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò máa gbọ́ tìrẹ. Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lúù rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú u Móṣè.

18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí ọ̀rọ̀ rẹ, tí kò sì ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ, nínú ohun gbogbo tí ìwọ yóò paláṣẹ fún wọn, pípa ni a ó pa á. Kí ìwọ ṣáà ṣe gírí, kí ó sì mú àyà le!”

Jóṣúà 1