Jóòbù 9:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.

26. Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eésú tí ń ṣúré lọ;bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.

27. Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi,èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’

28. Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí,èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.

29. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?

30. Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ ojú dídì wẹ ara mi,tí mo fi omi àrò wẹ ọwọ́ mi mọ́,

31. ṣíbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihòọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.

32. “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.

Jóòbù 9