Jóòbù 7:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Áà! Ránti pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi;ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́.

8. Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́;ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.

9. Bí ìkùùku tí i túká, tí í sì fò lọ,bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́.

10. Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.

11. “Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́,èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi,èmí yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.

12. Èmi a máa ṣe ejò òkun tàbí erinmi,tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?

Jóòbù 7