Jóòbù 6:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.

28. “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.Ẹ má wò mi! Nitorí pé ó hàn gbangba pé:Ní ojú yín ni èmi kì yóò sèké.

29. Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.

30. Àìṣedédé ha wà ní ahọ́n mi?Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?

Jóòbù 6