20. Nínu ìyànu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikúàti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
21. A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́nbẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.
22. Ìrin ìparun àti ti ìyàn ni ìwọ yóò rìnbẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé.
23. Nitorí pé ìwọ ó bá òkúta ìgbẹ́ múlẹ̀,àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.
24. Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wàìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò sìnà.
25. Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú ọmọ rẹ ó sì pọ̀àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko ìgbẹ́.
26. Ìwọ yóò wọ iṣà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́,bí àpò-ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.
27. “Kíyèsí i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí!Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.”