Jóòbù 5:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún talákààìsòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

17. “Kíyèsíi, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí,nítorí náà, má ṣe gan ìbàwí Olódùmarè.

18. Nítorí pé òun a mú ni lára kan,a sì di ìdì ìtura, ó ṣá lọ́gbẹ́, ọwọ́ rẹ̀ á sì mú jìnnà.

19. Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà,àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ

Jóòbù 5