Jóòbù 5:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Láti gbé àwọn orilẹ̀ èdè lékèkí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.

12. Ó yí ìmọ̀ àwọn alárèékérekè po,bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdàwọ́lé wọn sẹ.

13. Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú arékerekè ara wọn,àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tari ṣubú ní ògèdèǹgbé.

14. Wọ́n sáre wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sánwọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru.

15. Ṣùgbọ́n ó gba talákà là ní ọwọ́ idà,lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16. Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún talákààìsòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

Jóòbù 5