Jóòbù 42:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ígbà náà ní Jóòbù dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé:

2. “Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohungbogbo, àti pé, kò si ìro inú tí a lè fa sẹ́yìn kurò lọ́dọ̀ rẹ.

3. Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ làíní ìmọ̀?Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyití èmi kò mọ̀, ohun tí ó ṣe ìyànu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.

4. “Ìwọ wí pé, ‘gbọ́ tèmi báyìí,èmi ó sì sọ; èmi óbèèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’

5. Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́nnísinsìnyí ojú mi ti rí ọ.

Jóòbù 42