3. Nígbà náà ni Jóòbù dá Olúwalóhùn wá ó sì wí pé,
4. “Kíyèsí i, èmi kò jámọ́ ohun kankan;ohun kí ni èmi ó dà? Èmi ó fi ọwọ́ le ẹnu mi.
5. Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kòrí ìdáhùn kankan; lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì ní sọ ọ́ mọ́.”
6. Nígbà náà ní Olúwa sọ̀rọ̀ fún unláti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:
7. “Di àmùrè gíri ní ẹgbẹ́ rẹ, èmi ó biọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
8. “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo
9. Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lèfi ohùn sán àrá bí òun?