Jóòbù 40:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa dá Jóòbù lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wi pé:

2. “ẹni tí ń wá ẹ̀sùn yóò bá Olódùmarè wíjọ́ bí?Ẹni tí ń bá Ọlọ́run jiyàn jẹ́ kí ó dáhùn!”

3. Nígbà náà ni Jóòbù dá Olúwalóhùn wá ó sì wí pé,

4. “Kíyèsí i, èmi kò jámọ́ ohun kankan;ohun kí ni èmi ó dà? Èmi ó fi ọwọ́ le ẹnu mi.

5. Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kòrí ìdáhùn kankan; lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì ní sọ ọ́ mọ́.”

Jóòbù 40