Jóòbù 39:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. “Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́?Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́,

6. Èyí tí mo fi ihà ṣe ilé fún, àtiilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀

7. Ó rẹ́rìnín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ niÒun kò sì gbọ́ igbe darandaran.

8. Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjókòó rẹ̀,Òun asì má a wá ewé tútù gbogbo rí.

9. “Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí,ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?

10. Ìwọ le fi òkò tata de àgbáǹrérénínú aporo? Tàbí ó jẹ́ máa faìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?

11. Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀ lée nítorí agbára rẹ̀pọ̀ ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?

12. Ìwọ le gbẹ́kẹ̀ le pé, yóò mú èsooko rẹ̀ wá sílé, àti pé yóò sì kó ọ jọ sínu àká rẹ?

13. “Ìyẹ́ abo ògòǹgò ń fi ayọ̀ fì;Ṣùgbọ́n a kò le fi àká we ara wọn ní ìyẹ́ àti ìhùhù

14. Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀,a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;

Jóòbù 39