Jóòbù 39:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ìwọ mọ àkókò ìgbà tíàwọn ewúrẹ́ orí àpáta ìbímọ? Ìwọsì lè kíyèsí ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ?

2. Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pè,ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ,

3. Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bí mọ,wọ́n sì mú ìkáànú wọn jáde.

4. Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́ndàgbà nínú ọ̀dàn; wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.

5. “Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́?Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́,

6. Èyí tí mo fi ihà ṣe ilé fún, àtiilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀

7. Ó rẹ́rìnín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ niÒun kò sì gbọ́ igbe darandaran.

8. Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjókòó rẹ̀,Òun asì má a wá ewé tútù gbogbo rí.

9. “Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí,ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?

Jóòbù 39