14. Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdìamọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.
15. A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúròlọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga yóò sì ṣẹ́.
16. “Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí?Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?
17. A ha sílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ ríbí, ìwọ sì rí ilẹ̀kùn òjìji òkú?