16. Ìwọ mọ ti àwọ̀sánmọ̀ í fòó lọ,iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
17. Aṣọ rẹ̀ ti máa gbóná, nígbà tí ó fiatẹ́gùn ìhà gúsù mú ayé dákẹ́.
18. Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ódúró sinsin, tí ó sì dàbí dígi tí ó yọ̀ dà?
19. “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;nítorí pé àwa kò le ílàdí ọ̀rọ̀ nítorí òkùnkùn wa.
20. A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́sọ̀rọ̀? Tàbí ẹnìkan lèwí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbémi mù?
21. Ṣibẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò ríoòrùn tí ń dán nínú àwọ̀sánmọ̀,ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì fẹ́ wọn mọ́.