Jóòbù 37:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ayà sì fò mi si èyí pẹ̀lú, ósì kúro ní ìpò rẹ̀.

2. Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìróohùn rẹ̀, àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.

3. Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,Mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.

4. Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná Òun kan fọ̀ramúramù; ó sì fi ohùn ọláńlárẹ̀ sán àrá; òhun kì yóò sì dáàrá dúró nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.

5. Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá níọ̀nà ìyanu; ohùn ńláńlá ni íṣe tí àwa kò le mọ̀.

Jóòbù 37