27. “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omiọjọ́ sílẹ̀, kí wọn kí ó kán bí òjò ní odò,
28. tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀, tí ó sì fi ńgbìn lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.
29. Pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni lè imọ́ ìtànkáàwọ̀sánmọ̀, tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?
30. Kíyèsí i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ká ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.