Jóòbù 36:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀ra, àti ọdún wọn nínú afẹ́.

12. Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye.

13. “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní àyékó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá dà wọ́n.

14. Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú níèwe, ẹ̀mí wọn a sì wà nínú àwọn oníwà Sódómù.

15. Òun gba òtòsì nínú ìpọ́njú wọn,a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínu ìnira wọn.

Jóòbù 36