Jóòbù 35:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọfí fún u, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?

8. Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bíìwọ; òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.

9. “Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n múni kígbe; wọ́n kigbe nípa apá àwọn alágbára.

10. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níboni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;

11. Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọnẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wagbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’

12. Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́nỌlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.

13. Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ asán;bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.

14. Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì írí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ń bẹ níwájú rẹ,ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.

Jóòbù 35