Jóòbù 35:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọfí fún u, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?

8. Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bíìwọ; òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.

9. “Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n múni kígbe; wọ́n kigbe nípa apá àwọn alágbára.

10. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níboni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;

11. Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọnẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wagbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’

Jóòbù 35