Jóòbù 34:32-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi bimo bá sì dẹ́sẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

33. Íṣe bí ti inú rẹ̀ pe òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà?Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bíìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́ tàbíìwọ ìbá fẹ́ kì í ṣe èmi; Pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ!

34. “Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fúnmi, àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé,

35. ‘Jóòbù ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣealáìgbọ́n.’

Jóòbù 34