Jóòbù 34:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ta ni ó yàn ań lórí, tàbí ta ni ófi gbogbo ayé lée lọ́wọ́?

14. Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,

15. gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀,ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.

16. “Ǹjẹ́ nisinsìnyí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí;fetísí ohùn ẹnu mi.

17. Ẹni tí ó kóríra òtítọ́ ha le iṣe olóríbí? Ìwọ ó hà sì dá olóótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?

18. O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ènìyàn búburú ní ìwọ,tàbí fún àwọn ọmọ aládé pé, ìkà ni ẹ̀yin;

Jóòbù 34