Jóòbù 33:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ẹ̀mí Ọlọ́run Ní ó tí dá mi,Àti ìmísí Olódùmáre ni ó ti fún mi ní ìyè.

5. Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn,tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ṣẹẹsẹ níwájú mi; dìdé!

6. Kíyèsí i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run,bẹ́ẹ̀ ni èmí náà; láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú

7. Kíyèsí i, ẹrù ń lá mi kì yóò bà ọ;bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára.

8. “Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi, èmí sìgbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé,

Jóòbù 33