Jóòbù 32:16-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Mo si reti, nítorí wọn kò sìfọhún, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́; wọn kò sì dáhùn mọ́.

17. Bẹ́ẹ̀ ni èmí ò sì dáhùn nípa tièmí, èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.

18. Nítorí pé èmí kún fún ọ̀rọ̀ sísọ,èmí ń rọ̀ mi ni inú mi.

19. Kíyèsí i, ìkùn mi dàbí ọtí wáìnì,tí kò ní ojú-ìhò; ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-àwọ̀ tuntun.

20. Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí,èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.

21. Lótítọ́ èmí kì yóò ṣe ojúṣàájú síẹnìkankan, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.

Jóòbù 32