Jóòbù 31:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. (Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ̀n mí nínú ìwọ̀nòdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)

7. Bí ẹṣẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tíàyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbíbí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀mọ́ mi ní ọwọ́,

8. Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmìírànkí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú ọmọ mi tu.

9. “Bí àyà mi bá di fífà sípasẹ̀ obinrin kan,tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,

10. Ṣùgbọ́n kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fúnẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.

Jóòbù 31