23. Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí péwọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò wọn a sìmu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀-kúrò.
24. Èmi sì rẹ́rìn ín sí wọn nígbà tí wọnkò bá gbà á gbọ́; ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye síwọn.
25. Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sìjókòó bí olóyè wọn; mo jókòó bíọba ní àárin ológun rẹ̀; mo sìrí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń sọ̀fọ̀ nínú.