13. Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmisì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.
14. Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́mi dà bí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.
15. Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹṣẹ̀fún amúkùnún.
16. Mo ṣe baba fún talákà, mo ṣeìwádìí ọ̀ràn àjòjì tí èmi kò mọ̀ rí.
17. Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ìkà ènìyàn,mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.