Jóòbù 24:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró deàfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́; ‘Ó ní, ojúẹnìkan kì yóò rí mi;’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.

16. Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé,tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọnní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.

17. Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀fún gbogbo wọn; nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.

18. “Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun;òun kò rìn mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.

19. Ọ̀dá àti òru ní ímú omi ojọ-didi gbẹ, bẹ́ẹ̀ní isà òkú írun àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Jóòbù 24