12. Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá,ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́kígbe sókè; fún ìrànlọ́wọ́ ṣíbẹ̀Ọlọ́run kò kíyèsí àṣìṣe náà.
13. “Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó kọ̀ìmọ́lẹ̀; Wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.
14. Panipani a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́,a sì pa talákà àti aláìní, àti ní òru a di olè.
15. Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró deàfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́; ‘Ó ní, ojúẹnìkan kì yóò rí mi;’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.
16. Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé,tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọnní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.