Jóòbù 22:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Bí ó ṣe ti alágbára nì ni, òun ni óní ilẹ̀, ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀.

9. Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ níọwọ́ òfo; Apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́.

10. Nítorí náà ni ìdẹkùn ṣe yí ọkáàkiri, àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu,

11. Èé ṣe tí òkùnkùn, fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tíìwọ kò fi lè ríran; Èé ṣe tíọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12. “Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?Ṣá wò orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!

13. Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀?Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?

14. Àwọ̀sánmọ̀ tí ó nípọn ni ìborafún un, tí kò fi lè ríran; ó sì rìn nínú àyíká ọ̀run.

Jóòbù 22