Jóòbù 21:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pá iná Ọlọ́run kò sí lára wọn.

10. Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì ísìíṣe; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun;

11. Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọnwẹ́ẹ́wẹ́ẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jó kiri.

12. Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àtiháápù, wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè

13. Wọ́n ní ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọnsì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.

Jóòbù 21