Jóòbù 21:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jóòbù wá dahùn, ó sì wí pé:

2. “Ẹ tẹ́tí silẹ̀ dẹdẹ sì àwọn ọ̀rẹ́ mi,kí èyí kí ó jásí ìtùnú tí ó fún mi.

3. Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbàtí mo bá sọ tán, ìwọ máa fi ṣẹ̀sín ń ṣo.

4. “Bí ó ṣe tí èmi ni, àròyé mi iṣe sí ènìyàn bí?Tàbí èétíṣe tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?

5. Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín,kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.

6. Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí,ìwárìrì sì mú mi lára.

Jóòbù 21