Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa àṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á.