Jóòbù 19:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. “Kiyè sì í, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára;’ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdajọ́.

8. Ó sọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le èkọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.

9. Ó ti bọ́ ògo mi,ó sì sí adé kúrò ní orí mi.

10. Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.

Jóòbù 19