5. Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si milórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,
6. Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni óbì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
7. “Kiyè sì í, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára;’ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdajọ́.
8. Ó sọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le èkọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
9. Ó ti bọ́ ògo mi,ó sì sí adé kúrò ní orí mi.
10. Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
11. Ó sì tinábọ ìbínú rẹ̀ sími,ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.