Jóòbù 17:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ẹni tí ó fi àwọn ọ̀rẹ́ hàn fúnìgárá, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.

6. “Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fúnàwọn ènìyàn; níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.

7. Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́,gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.

8. Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí,ẹni aláìsẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.

9. Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,àti ọlọ́wọ́ mímì yóò máa lera síwájú.

Jóòbù 17