Jóòbù 17:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ẹ̀mí mi bàjẹ́,ọjọ́ mi ni a tigé kúrú, ìsà òkú dúró dè mí.

2. Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà h wà lọ́dọ̀ mi,ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.

3. “Ǹjẹ́ nísinsínyí, fi lélẹ̀ yàn onígbọ̀wọ́fún mi lọ́dọ̀ rẹ; ta ni Olúwa tí yóò le ṣe ààbò fún mi?

4. Nítorí pé ìwọ ti ṣé wọ́n láyà kúrònínú òyè; nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.

Jóòbù 17