Jóòbù 15:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Òun sì gbé inú ahoro ìlú ìtakété,àti nínú iléyílé tí ènìyàn kò gbémọ́, tí ó múra tán lati di àlàpà.

29. Òun kò lé ìlà, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kòlè dúró pẹ́; Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

30. Òun kì yóò jáde kúrò nínúòkùnkùn; ọ̀wọ́ iná ni yóò jóẹ̀ka rẹ̀, àti nípaṣẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ní yóò máa kọjá lọ kúrò.

31. Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀le asán,kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.

32. A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípẹ́ ọjọ́ rẹ̀,ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.

Jóòbù 15