Jóòbù 15:16-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ańbọ̀tórí ènìyàn, ẹni ìríra àtieléèérìí, tí ń mù ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mú omi.

17. “Èmi ó fihàn ọ́: gbọ́ ti èmi; Èyí tíèmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,

18. tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn latiọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,

19. Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.

20. Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lúìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iyeọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.

21. Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.

Jóòbù 15