Jóòbù 14:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ ń káye ìsísẹ̀ mi;ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?

17. A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,ìwọ sì rán àìṣedédé mi pọ̀.

18. “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ódasán, a sì sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.

19. Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sìmú omi ṣàn bo ohun tí ó hù jáde lóri ilẹ̀,ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.

20. Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjálọ; Ìwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.

Jóòbù 14