12. bẹ́ẹ̀ ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.
13. “Áà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
14. Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
15. Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ ń káye ìsísẹ̀ mi;ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
17. A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,ìwọ sì rán àìṣedédé mi pọ̀.