11. Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí?Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?
12. Ìrántí yín dàbí eérú;Ìlú odi yín ìlú odi amọ̀.
13. “Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi,kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀, ohun tí ńbọ̀ wá íbá mi, kí ó máa bọ̀.
14. Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi èyín mibu ẹran ara mi jẹ, Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?
15. Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e;Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.