18. “Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá?Áà! èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi
19. Tí ó bá lejẹ́ pé èmi le wà láàyè,À bá ti gbé mi láti inú lọ isà-òkú.
20. Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárádáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ minítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan
21. Kí èmi kí ó tó lọ síbi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́,Àní kí ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú,
22. Ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkárarẹ̀,Àti ti òjìji ikú, láìní ìtọ́,Níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”